Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 9:23-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Má ṣe jẹ́ kí ọlọgbọ́n yangànnítorí ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbáranítorí rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀nítorí ọrọ̀ rẹ̀.

24. Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ńṣògo nípa èyí nì wí péòun ní òye, òun sì mọ̀míwí pé, Èmi ni Olúwa tí ńṣe òtítọ́ ìdájọ́ àti òdodoní ayé nínú èyí ni mo níinú dídùn sí,” Olúwa wí.

25. “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan.

26. Éjíbítì, Júdà, Édómù, Ámónì, Móábù àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jínjìn réré ní ihà. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Ísírẹ́lì sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 9