Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 8:16-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ìró ìfọnmú ẹsin àwọn ọlọ̀tẹ̀ là ńgbọ́ láti Dánì yíyan àwọn akọ ẹsinmú gbogbo ilẹ̀ wárìrì. Wọ́n wá látipa ilẹ̀ náà run, gbogbo ohun tówà níbẹ̀, ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀.”

17. “Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró síàárin yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa orówọn, yóò sì bù yín jẹ,”ni Olúwa wí.

18. Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mirẹ̀wẹ̀sì nínú mi.

19. Fetí sí igbe àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ tó jìn:“Olúwa kò ha sí ní Síóní bí?Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?”“È é ṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọnòrìṣà àjòjì tí wọn kò ní láárí?”

20. “Ìkóórè ti ré kọ́ja, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti paríṣíbẹ̀, a kò gbà wá là.”

21. Níwọ̀n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run,èmi náà run pẹ̀lú, mo sọ̀fọ, ìrora sì mú mi káká.

Ka pipe ipin Jeremáyà 8