Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 52:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ní Ríbílà ni Ọba Bábílónì ti pa ọmọkùnrin Sedekáyà lójú rẹ̀; ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Júdà.

11. Lẹ́yìn náà, o yọ ojú Ṣedekáyà síta, o sì fi ẹ̀wọ̀n yìí dì í, ó sì gbe e lọ sí Bábílónì níbi tí ó ti fi sínú ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n títí di ikú ọjọ́ rẹ̀.

12. Ní ọjọ́ kẹ́wàá oṣù kárùn-ún ní ọdún kọkàndínlógún Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù.

Ka pipe ipin Jeremáyà 52