Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 52:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣédékáyà jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ Ọba. Ọdún mọ́kànlá ló fi jọba ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútalì ọmọ Jeremáyà; láti Líbíná ló ti wá.

2. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa gẹ́gẹ́ bí Jéhóáikímù ti ṣe

3. Nítorí ìbínú Olúwa ni gbogbo èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà àti ní ìkẹyìn. Ó sì gbà wọ́n gbọ́ ní iwájú rẹ̀. Sedekáyà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọba Bábílónì.

4. Nígbà tí ó di ọdún kẹ́sàn án ti Sedekáyà tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹ́wàá, oṣù kẹ́wàá Nebukadinésárì Ọba Bábílónì sì lọ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà; wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀.

5. Ìlú náà sì wá lábẹ́ ìhámọ́ títí di ọdún kọkànlá Ọba Sédékáyà.

6. Ní ọjọ́ kẹ́sàn án, oṣù mẹ́rin ìyàn ìlú náà sì ti burú dé ibi pé kò sí oúnjẹ kankan mọ́ fún àwọn ènìyàn láti jẹ.

7. Bákan náà, odi ìlú náà ti ya àwọn ọmọ ogun sì tí sálọ. Wọn fi ìlú náà sílẹ̀ ní òru nípa ojú ọ̀nà tó wà láàrin odi méjèèjì lẹ́bàá ọgbà Ọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Àwọn ará Bábílónì yìí yí ìlú náà ká. Wọ́n sá gba aginjù lọ.

8. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ogun Bábílónì lépa Ọba Sedekáyà wọ́n sì le bá ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò. Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì pínyà, kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì túká.

9. Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn. Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Bábílónì, ní Ríbíla ní ilẹ̀ Hámátì níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.

10. Ní Ríbílà ni Ọba Bábílónì ti pa ọmọkùnrin Sedekáyà lójú rẹ̀; ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Júdà.

11. Lẹ́yìn náà, o yọ ojú Ṣedekáyà síta, o sì fi ẹ̀wọ̀n yìí dì í, ó sì gbe e lọ sí Bábílónì níbi tí ó ti fi sínú ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n títí di ikú ọjọ́ rẹ̀.

12. Ní ọjọ́ kẹ́wàá oṣù kárùn-ún ní ọdún kọkàndínlógún Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù.

13. Ó dáná sun pẹpẹ Olúwa, ààfin àti gbogbo àwọn ilé Jérúsálẹ́mù. Ó sì dáná sun gbogbo àwọn ilé ńláńlá.

14. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí wọ́n wà lábẹ́ àṣẹ balógun ìṣọ́ wó gbogbo odi tí ó yí ìlú Jérúsálẹ́mù lulẹ̀.

15. Nebusarádánì balógun ìsọ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú náà lọ sí ilẹ̀ àjèjì pẹ̀lú àwọn oníṣọ̀nà tí ó kù àti gbogbo àwọn tí ó ti lọ sọ́dọ̀ Ọba Bábílónì.

16. Ṣùgbọ́n Nebukadinésárì fi àwọn tálákà tó kú ní ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà àti oko.

17. Àwọn Bábílónì fọ́ idẹ ìpìlẹ̀ àti àwọn ìjókòó tó ṣe é gbé kúrò àti àwọn ìdè wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní pẹpẹ Olúwa. Wọ́n sì kó gbogbo idẹ náà lọ sí Bábílónì.

Ka pipe ipin Jeremáyà 52