Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 49:30-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. “Sálọ kíákíá, dúró nínú ihòìwọ tí ò ń gbé Ásórì,”báyìí ni Olúwa wí.“Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ti dojú ìjà kọ ọ́.

31. “Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀ èdèkan pẹ̀lú ìrọ̀rùn, èyítí ó dúró pẹ̀lú ìgboyà;”báyìí ní Olúwa wí.“Orílẹ̀ èdè tí kò ní yálà gbàgede tàbí irin,àwọn ènìyàn re ń dágbé.

32. Àwọn ràkunmí á di ẹrùàti àwọn agbo àgùntàn, wọ́n á di ìkógun.Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́.Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,”báyìí ní Olúwa wí.

33. “Ásọ́rì yóò di ibi ìdọdẹ àwọnakáta, ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé,kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.”

34. Èyí ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyí tí ó tọ Jeremáyà wòlíì wá nípa Élámù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekáyà Ọba Júdà:

35. Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ:“Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Élámù,ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.

36. Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rinàgbáyé lòdì sí Élámù.Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rinàti pé, kò sí orílẹ̀ èdè tí ilẹ̀ àjèjì Élámù kò ní lọ.

37. Èmi yóò kẹ́gàn Élámù lójúàwọn ọ̀tá rẹ̀ àti lọ́dọ̀ àwọntí wọ́n jọ ń gbé.Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn,pàápàá ìbínú gbígbóná mi;”bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.“Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn.

38. Èmi yóò sì pa Ọba wọn run àti olórí wọn,”báyìí ni Olúwa wí.

39. “Ṣíbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọẸ́lámù padà láìpẹ́ ọjọ́,”báyìí ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Jeremáyà 49