Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 48:26-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. “Ẹ jẹ́ kí a mú u mutínítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa,jẹ́ kí Móábù pàfọ̀ nínú èébì rẹ̀,kí ó di ẹni ẹ̀gàn.

27. Ǹjẹ́ Ísírẹ́lì kò di ẹni ẹ̀gan rẹ?Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olètó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́nígbákùúgbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

28. Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrin àwọn òkúta,ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Móábù.Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀sí ẹnu ihò.

29. “A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù:àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀.

30. Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,”ni Olúwa wí,“ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkankan.

31. Nítorí náà, mo pohùnréréẹkún lórí Móábù fún àwọnará Móábù ni mo kígbe lóhùn raraMo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kíháráṣè.

32. Mo sunkún fún ọ bí Jásì ṣe sunkúnìwọ àjàrà Síbínà.Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé òkun wọn,Ámónì,ajẹnirun ti kọlu èṣo rẹàti àwọn èṣo àjàrà rẹ.

33. Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrònínú ọgbà àjàrà àti okoMóábù, mo dá ọwọ́ṣíṣàn ọtí wáìnì dúrólọ́dọ̀ olùfúnni; kò sí ẹni tíó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ti ayọ̀.

34. “Ohùn igbe wọn gòkè látiHésíbónì dé Élíà àti Jásìláti Sóà títí dé Hórónáímùàti Éjíbítì Sélíáyà, nítoríàwọn omi Nímírímù pẹ̀lú ti gbẹ

35. Ní ti Móábù ni èmi yóò ti fiòpin sí ẹni tí ó rúbọsí ibí gíga àti ẹni tí ń suntùràrí fún òrìṣà rẹ̀,”ni Olúwa wí.

36. “Nítorí náà ọkàn mi rófún Móábù bí fèrè oróHíhárésétì ìṣúra ńlátí wọ́n kójọ ṣègbé.

37. Gbogbo orí mi ni ó pá,gbogbo irungbọ̀n ni a gé kúrò,gbogbo ọwọ́ ni a ṣá lọ́gbẹ́, àtiaṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́.

38. Ní gbogbo orílẹ̀ èdèMóábù àti ní ita kò síohun kan bí kò ṣe ọ̀fọ̀, nítorítí mo fọ́ Móábù bí a ti ń fọ́ohun elò tí kò wu ni,”ni Olúwa wí.

39. “Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú,tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún!Báwo ni Móábù ṣe yíẹ̀yìn padà ní ìtìjú!Móábù ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àtiìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká.”

40. Báyìí ni Olúwa wí:“Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Móábù.

41. Koríko kan yóò di kíkóàti àwọn ìlú olódì.Ní ọjọ́ náà ọkàn akọni Móábùyóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí.

42. A ó pa Móábù run gẹ́gẹ́ bíorílẹ̀ èdè nítorípé ó gbéraga sí Olúwa.

43. Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídèń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Móábù,”ní Olúwa wí.

44. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fúnẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìnẹnikẹ́ni tí o bá jáde sítanínú ọ̀fìn ní à ó múnínú okùn dídè nítorí tíèmi yóò mú wá sóríMóábù àní ọdún Ìjìyà rẹ,”ní Olúwa wí.

45. “Ní abẹ́ òjìji Hésíbónìàwọn tí ó sá dúró láìníolùrànlọ́wọ́ nítorí iná ti jáde wáláti Hésíbónì àti ọwọ́ ináláti àárin Síónì sì jó iwájú orí Móábù runàti agbárí àwọn ọmọ àlùfáà.

46. Ègbé ní fún ọ Móábù!Wọn yóò sì kó àwọn ọmọkùnrin yín lọ síilẹ̀ àjèjì àti àwọn ọmọbìnrin yín lọ sí ìgbékùn.

Ka pipe ipin Jeremáyà 48