Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 48:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nípa Móábù:Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí:“Ègbé ni fún Nébò nítorí a ó parun.A dójú ti Kíríátaímù, a sì mú un,ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká.

2. Móábù kò ní ní ìyìn mọ́,ní Héṣíbónì ni wọn ó pète ìparun rẹ̀,‘Wá, kí a pa orílẹ̀ èdè náà run.’Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́,a ó fi idà lé e yín.

3. Gbọ́ igbe ní Horonáímù,igbe ìrora àti ìparun ńlá.

4. Móábù yóò di wíwó palẹ̀;àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta.

5. Wọ́n gòkè lọ sí Lúhítì,wọ́n ń sunkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ;ní ojú ọ̀nà sí Horonáímùigbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ.

6. Sá! Àsálà fún ẹ̀mí rẹ;kí o dàbí igbó ní aṣálẹ̀.

7. Níwọ̀n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ,a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn,Sémọ́sì náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùnpẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀.

8. Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ,ìlú kan kò sì ní le là.Àfonífojì yóò di ahoroàti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run,nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin Jeremáyà 48