Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 48:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nípa Móábù:Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí:“Ègbé ni fún Nébò nítorí a ó parun.A dójú ti Kíríátaímù, a sì mú un,ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká.

2. Móábù kò ní ní ìyìn mọ́,ní Héṣíbónì ni wọn ó pète ìparun rẹ̀,‘Wá, kí a pa orílẹ̀ èdè náà run.’Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́,a ó fi idà lé e yín.

3. Gbọ́ igbe ní Horonáímù,igbe ìrora àti ìparun ńlá.

Ka pipe ipin Jeremáyà 48