Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 46:14-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. “Kéde èyí ní Éjíbítì, sì sọ ọ́ ní Nígídò,sọ ọ́ ní Mémífísì àti Táfánésì:‘Dúró sí àyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀,nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’

15. Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú?Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú.

16. Wọn yóò máa ṣubú léralérawọn yóò máa ṣubú lu ara wọn.Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padàsí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa,kúrò níbi idà àwọn aninilára.’

17. Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé,‘Ariwo lásán ni Fáráò Ọba Éjíbítì pa,ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’

18. “Bí èmi ti wà láàyè,” ni Ọba,ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ ogun wí pé,“nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tábórì láàrin àwọn òkè àtigẹ́gẹ́ bi Kámẹ́lì lẹ́bàá òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé.

19. Iwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Éjíbítì pèsèohun èlò ìrìn-àjò fún ara rẹnítorí Nófù yóò di ahoro a ó sì fi jóná,láìní olùgbé.

20. “Ẹgbọ̀rọ̀ abo màlúù tó lẹ́wà ní Éjíbítìṣùgbọ́n eṣinṣintí yóò le ń bọ̀ láti àríwá.

21. Àwọn jagunjagun rẹ̀dàbí àbọ́pa màlúù.Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà,wọn ó sì jùmọ̀ sá,wọn kò ní le dúró,Nítorí tí ọjọ́ ibi ńbọ̀ lórí wọnàsìkò láti jẹ wọ́n níyà.

22. Éjíbítì yóò pòṣé bí ejò tí ń sábí ọmọ ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára.Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké,gẹ́gẹ́ bí i ti agégi.

23. Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,”ni Olúwa wí,“nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀,nítorí pé wọ́n pọ̀ ju elẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye.

Ka pipe ipin Jeremáyà 46