Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 41:8-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ṣùgbọ́n mẹ́wàá nínú wọn sọ fún Ísímáẹ́lì pé, “Má se pa wá! Àwa ní ọkà àti Bálì, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀: kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn yóòkù.

9. Nísinsìn yìí, ihò náà tí ó kó gbogbo ara àwọn ọkùnrin tí ó ti pa pẹ̀lú Jedaláyà sí ni Ọba Aṣa ń lò gẹ́gẹ́ bí i ààbò nítorí Ọba Báṣì ti Ísírẹ́lì. Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà sì ti kó òkú kún inú rẹ̀.

10. Ísímáẹ́lì sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mísípà nígbèkùn, ọmọbìnrin Ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tó kù síbẹ̀ lórí àwọn tí Nebusarádánì balógun àwọn ẹ̀sọ́ ti fi yan Gédáláyà ọmọkùnrin Álíkámù ṣe olórí. Isímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà kó wọn ní ìgbèkùn, ó sì jáde rékọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn Ámónì.

11. Nígbà tí Johánánì ọmọkùnrin Kárè àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ nípa gbogbo ìpànìyàn náà tí Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà ti ṣe.

12. Wọ́n kó gbogbo àwọn ọkùnrin wọn, wọ́n sì, lọ bá Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà jà. Wọ́n pàdé rẹ̀ ní odò kan lẹ́bàá Gídéónì.

13. Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn Ísímáẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ rí Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì yọ̀.

14. Gbogbo àwọn ènìyàn tí Ísímáẹ́lì ti kó ní ìgbékùn ní Mísípà yípadà, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Jóhánánì ọmọ Káréà.

Ka pipe ipin Jeremáyà 41