Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 41:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní oṣù keje Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, ọmọkùnrin Élísámà ti ìdílé Ọba, tí ó sì ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè Ọba, tọ Jedaláyà ọmọ Áhíkámù ti Mísípà wá pẹ̀lú ọkùnrin mẹ́wàá. Nígbà tí wọ́n ń jẹun papọ̀.

2. Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Jedaláyà ọmọ Áhíkámù, ọmọ Sáfánì pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí Ọba Bábílónì ti yàn gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí ilẹ̀ náà.

3. Íṣímáẹ́lì sì tún pa gbogbo àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú Jedaláyà ní Mísípà, àti gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí wọ́n wà níbẹ̀ bákan náà.

4. Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n pa Jedaláyà kí ó tó di wí pé ẹnikẹ́ni mọ̀

5. Àwọn ọgọ́rin ọkùnrin wá láti Ṣékémù, Ṣílò àti Saaríà, wọ́n fa irùngbọ̀n wọn, wọ́n ya aṣọ wọn, wọ́n sá ara wọn lọ́gbẹ́ wọ́n mú ẹbọ ọpẹ́ àti tùràrí wá sí ilé Olúwa.

6. Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà jáde kúrò láti Mísípà láti lọ pàdé wọn. Ó sì ń sunkún bí ó ti ṣe ń lọ, nígbà tí ó pàdé wọn, ó wí pé, “Ẹwá sọ́dọ̀ Jedaláyà ọmọkùnrin Álíkámù.”

7. Nígbà tí wọ́n dé ìlú náà; Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nètanáyà àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì sọ òkú wọn sínú ìhò kan.

Ka pipe ipin Jeremáyà 41