Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 4:9-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí pé,“àwọn Ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn,àwọn àlùfáà yóò wárìrì,àwọn wòlíì yóò sì fòyà.”

10. Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Áà! Olúwa àwọn ọmọ-ogun, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jérúsálẹ́mù jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o fẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.”

11. Nígbà náà ni a ó sọ fún Jérúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́.

12. Ẹ̀fúùfù líle tí ó wá láti ọ̀dọ̀ mi. Báyìí mo kéde ìdájọ́ mi lórí wọn.”

13. Wò ó! O ń bò bí ìkuukùukẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líleẸ̀ṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọÈgbé ni fún wa àwa parun.

14. Ìwọ Jérúsálẹ́mù, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yèYóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ?

15. Ohùn kan sì ń kéde ní DánìÓ ń kókìkí ìparun láti orí òkè Éfúráímù wá.

16. “Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀ èdè,kéde rẹ̀ fún Jérúsálẹ́mù pé:‘Ọmọ ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jínjìn wáWọ́n sì ń kígbe ogun láti dojú kọ ìlú Júdà.

17. Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá,nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ”ni Olúwa wí.

18. “Ìwà rẹ àti ìṣe rẹló fa èyí bá ọÌjìyà rẹ sì nìyìí,Báwo ló ti ṣe korò tó!Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!”

19. Áà! Ìrora mi, ìrora mi!Mo yí nínú ìrora.Áà!, ìrora ọkàn mi!Ọkàn mi lù kìkì nínú mi,N kò le è dákẹ́.Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè,Mo sì ti gbọ́ igbe ogun.

Ka pipe ipin Jeremáyà 4