Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 4:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá,nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ”ni Olúwa wí.

18. “Ìwà rẹ àti ìṣe rẹló fa èyí bá ọÌjìyà rẹ sì nìyìí,Báwo ló ti ṣe korò tó!Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!”

19. Áà! Ìrora mi, ìrora mi!Mo yí nínú ìrora.Áà!, ìrora ọkàn mi!Ọkàn mi lù kìkì nínú mi,N kò le è dákẹ́.Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè,Mo sì ti gbọ́ igbe ogun.

20. Ìparun ń gorí ìparun;Gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparunLọ́gán a wó àwọn àgọ́ mi,tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan.

21. Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí oguntí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè?

22. “Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi;wọn kò mọ̀ mí.Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ;wọ́n sì jẹ́ aláìlóye.Wọ́n mọ ibi ṣíṣe;wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 4