Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 37:13-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ẹnu-bodè Bẹ́ńjámínì, olórí àwọn olùṣọ́ tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Íríjà ọmọ Ṣelemáyà ọmọ Hananáyà mú un, ó wí pé, “Ìwọ ń yapa sí àwọn ará Bábílónì.”

14. Jeremáyà sọ wí pé, “Èyí kì í ṣe òtítọ́! Èmi kò yapa sí àwọn ará Bábílónì.” Ṣùgbọ́n Íríjà kọ tí ikún sí i, dípò èyí a mú Jeremáyà, ó sì mú un lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìjòyè.

15. Wọ́n bínú sí Jeremáyà, wọ́n jẹ ẹ́ níyà, wọ́n tún fi sí àtìmọ́lé nílé Jónátanì akọ̀wé nítorí wọ́n ti fi èyí ṣe ilé túbú.

16. Wọ́n fi Jeremáyà sínú túbú tí ó ṣókùnkùn biribiri; níbi tí ó wà fún ìgbà pípẹ́.

17. Nígbà náà ni Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ sí i, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú wá sí ààfin níbi tí ó ti bi í ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Ìfẹ́ ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?”“Bẹ́ẹ̀ ni,” Jeremáyà fèsì pé, “wọn ó fi ọ́ lé ọwọ́ Ọba Bábílónì.”

18. Nígbà náà, Jeremáyà sọ fún Ọba Sedekáyà pé, “Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ yín, àwọn ìjòyè yín pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ẹ fi sọ mí sínú túbú?

19. Níbo ni àwọn wòlíì yín tí wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ fún-un yín wí pé Ọba Bábílónì kò ní gbógun tì yín wá?

20. Ṣùgbọ́n ní báyìí, Olúwa mi Ọba jọ̀wọ́ gbọ́. Jẹ́ kí n mú ẹ̀dùn ọkàn mi tọ̀ ọ́ wá; má ṣe rán mi padà sí ilé Jónátanì akọ̀wé, à fi kí n kú síbẹ̀.”

21. Ọba Sedekáyà wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi Jeremáyà sínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, àti kí wọn sì fún ní àkàrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí àkàrà yóò fi tán; bẹ́ẹ̀ ni Jeremáyà wà nínú àgbàlá náà.

Ka pipe ipin Jeremáyà 37