Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 34:7-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nígbà tí ogun Ọba Bábílónì ń bá Jérúsálẹ́mù jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù ní Júdà, Lákíṣì, Ásékà; àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Júdà.

8. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremáyà wá lẹ́yìn ìgbà tí Ọba Sedekáyà ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú.

9. Kí oníkálùkù lè jẹ́ kí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin tí í ṣe Hébérù lọ lọ́fẹ̀ẹ́, kí ẹnikẹ́ni kí ó má mú ará Júdà arákùnrin rẹ̀ sìn.

10. Nítorí náà, gbogbo àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọwọ́ sí májẹ̀mú náà láti dá ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin sílẹ̀ kí wọ́n sì má ṣe fi wọ́n sínú ìgbékùn mọ́. Wọ́n sì gbà, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ lọ́fẹ̀ẹ́

11. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n yí ọkàn wọn padà; wọ́n sì mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀ padà láti tún máa sìn wọ́n.

12. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé:

13. “Èyí ni ohun tí Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: Mo dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín nígbà tí mo mú wọn kúrò ní Éjíbítì; kúrò ní oko ẹrú. Mo wí pé,

14. ‘Ní ọdún keje, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ tú àwọn Hébérù tí wọ́n ti ta ara wọn fún un yín sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti sìn yín fún ọdún mẹ́fà. Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn kí ó lọ’; ṣùgbọ́n àwọn baba yín kò gbọ́; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sími.

15. Láìpẹ́ yìí ẹ ti ronúpìwàdà, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì ṣe ìtúsílẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Ẹ sì tún bá mi dá májẹ̀mú ní àwọn ilé tí a ti ń pe orúkọ mi.

Ka pipe ipin Jeremáyà 34