Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 34:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. “ ‘Síbẹ̀, gbọ́ ìlérí Olúwa, ìwọ Sedekáyà Ọba Júdà. Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí nípa rẹ; ìwọ kì yóò ti ipa idà kú;

5. Ìwọ yóò kú ní àlàáfíà. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń ṣe iná ìsìnkú ní ọlá fún àwọn baba rẹ, Ọba tí ó jẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe iná ní ọlá rẹ, wọn ó sì pohùnréré pé, “Yé, olúwa!” Èmi fúnra mi ni ó ṣèlérí yìí ni Olúwa wí.’ ”

6. Nígbà náà ni Jeremáyà wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekáyà Ọba Júdà ní Jérúsálẹ́mù.

Ka pipe ipin Jeremáyà 34