Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 34:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ Ọba tí ó jọba lé lórí ń bá Jérúsálẹ́mù jà, àti gbogbo àwọn ìlú tí ó yí ká, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa pé:

2. “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ọmọ ogun wí: Lọ sí ọ̀dọ̀ Sedekáyà Ọba Júdà kí o sì sọ fún-un pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Èmi fẹ́ fa orílẹ̀ èdè yìí lé Ọba Bábílónì lọ́wọ́, yóò sì jó palẹ̀.

3. Ìwọ kò ní sá àsálà, ṣùgbọ́n à ó mú ọ, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́. Ìwọ yóò rí Ọba Bábílónì pẹ̀lú ojú ara rẹ; yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú; ìwọ yóò sì lọ sí Bábílónì.

4. “ ‘Síbẹ̀, gbọ́ ìlérí Olúwa, ìwọ Sedekáyà Ọba Júdà. Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí nípa rẹ; ìwọ kì yóò ti ipa idà kú;

5. Ìwọ yóò kú ní àlàáfíà. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń ṣe iná ìsìnkú ní ọlá fún àwọn baba rẹ, Ọba tí ó jẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe iná ní ọlá rẹ, wọn ó sì pohùnréré pé, “Yé, olúwa!” Èmi fúnra mi ni ó ṣèlérí yìí ni Olúwa wí.’ ”

6. Nígbà náà ni Jeremáyà wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekáyà Ọba Júdà ní Jérúsálẹ́mù.

7. Nígbà tí ogun Ọba Bábílónì ń bá Jérúsálẹ́mù jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù ní Júdà, Lákíṣì, Ásékà; àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Júdà.

8. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremáyà wá lẹ́yìn ìgbà tí Ọba Sedekáyà ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú.

9. Kí oníkálùkù lè jẹ́ kí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin tí í ṣe Hébérù lọ lọ́fẹ̀ẹ́, kí ẹnikẹ́ni kí ó má mú ará Júdà arákùnrin rẹ̀ sìn.

10. Nítorí náà, gbogbo àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọwọ́ sí májẹ̀mú náà láti dá ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin sílẹ̀ kí wọ́n sì má ṣe fi wọ́n sínú ìgbékùn mọ́. Wọ́n sì gbà, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ lọ́fẹ̀ẹ́

11. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n yí ọkàn wọn padà; wọ́n sì mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀ padà láti tún máa sìn wọ́n.

12. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé:

13. “Èyí ni ohun tí Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: Mo dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín nígbà tí mo mú wọn kúrò ní Éjíbítì; kúrò ní oko ẹrú. Mo wí pé,

Ka pipe ipin Jeremáyà 34