Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 33:21-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Léfì tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dáfídì kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.

22. Èmi ó mú àwọn ọmọlẹ́yìn Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti Léfì tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú òkun tí kò ṣe é wọ̀n.’ ”

23. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé:

24. “Ǹjẹ́ ìwọ kò kíyèsí pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ pé: ‘Olúwa ti kọ àwọn Ọba méjèèjì tí ó yàn sílẹ̀’? Nítorí náà, ni wọ́n ti ṣe kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi. Wọn kò sì mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè kan.

25. Báyìí ni Olúwa wí: ‘Bí èmi kò bá ti da májẹ̀mú mi pẹ̀lú ọ̀sán àti òru àti pẹ̀lú òfin ọ̀run àti ayé tí kò lè yẹ̀.

26. Nígbà náà ni èmi ó kọ ọmọlẹ́yìn Jákọ́bù àti Dáfídì ìránṣẹ́ mi tí èmi kò sì ní yan ọ̀kan nínú ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ alákóso lórí àwọn ọmọlẹ́yìn Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù; nítorí èmi ó mú ìkólọ wọn padà; èmi ó sì ṣàánú fún wọn.’ ”

Ka pipe ipin Jeremáyà 33