Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 33:19-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremáyà wá wí pé:

20. “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Tí ìwọ bá lè dá májẹ̀mú mi ní òru tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀sán àti òru kò lè sí ní àkókò wọn mọ́.

21. Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Léfì tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dáfídì kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.

22. Èmi ó mú àwọn ọmọlẹ́yìn Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti Léfì tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú òkun tí kò ṣe é wọ̀n.’ ”

23. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé:

24. “Ǹjẹ́ ìwọ kò kíyèsí pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ pé: ‘Olúwa ti kọ àwọn Ọba méjèèjì tí ó yàn sílẹ̀’? Nítorí náà, ni wọ́n ti ṣe kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi. Wọn kò sì mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè kan.

25. Báyìí ni Olúwa wí: ‘Bí èmi kò bá ti da májẹ̀mú mi pẹ̀lú ọ̀sán àti òru àti pẹ̀lú òfin ọ̀run àti ayé tí kò lè yẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremáyà 33