Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 33:16-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì, Júdà yóò di ẹni ìgbàlà.Jérúsálẹ́mù yóò sì máa gbé láìséwuOrúkọ yìí ni a ó máa pè é Olúwa wa olódodo.’

17. Nítorí báyìí ni Olúwa wí: ‘Dáfídì kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Ísírẹ́lì.

18. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Léfì kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun; ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ.’ ”

19. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremáyà wá wí pé:

20. “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Tí ìwọ bá lè dá májẹ̀mú mi ní òru tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀sán àti òru kò lè sí ní àkókò wọn mọ́.

21. Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Léfì tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dáfídì kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.

22. Èmi ó mú àwọn ọmọlẹ́yìn Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti Léfì tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú òkun tí kò ṣe é wọ̀n.’ ”

23. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé:

Ka pipe ipin Jeremáyà 33