Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 32:5-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Yóò mú Sedekáyà lọ sí Bábílónì tí yóò wà títí èmi yóò fi bẹ̀ ọ́ wò ni Olúwa wí. Tí ẹ̀yin bá bá àwọn ará Kálídéà jà, ẹ̀yin kì yóò borí wọn.’ ”

6. Jeremáyà wí pé, “ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

7. Hánámélì ọmọkùnrin Sálúmù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò tọ̀ ọ́ wá pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì; nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó sún mọ́ wọn, ẹ̀tọ́ àti ìṣe rẹ ní láti rà á.’

8. “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì tí ó wà ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’“Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí.

9. Bẹ́ẹ̀ ni; èmi ra pápá náà ní Ánátótì láti ọwọ́ Hánámélì ọmọ ẹ̀gbọ́n mi. Ó sì wọn ìwọn ṣékélì àti fàdákà mẹ́tadínlógún fún un.

10. Mo fọwọ́ sínú ìwé, mo sì dì í pa. Mo pe ẹlẹ́rìí síi, mo sì wọn fàdákà náà lórí òṣùwọ̀n.

11. Mo mú ìwé tí mo fi rà á, èyí tí a di pa nípa àṣẹ àti òfin wa, àti èyí tí a kò lẹ̀.

12. Èmi sì fi èyí fún Bárúkì ọmọkùnrin ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá túbú.

Ka pipe ipin Jeremáyà 32