Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 32:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Àwọn ogun Ọba Bábílónì ìgbà náà há Jérúsálẹ́mù mọ́. A sì ṣé wòlíì Jeremáyà mọ́ inú túbú tí wọ́n ń sọ́ ní àgbàlá ilé Ọba Júdà.

3. Nítorí Sedekáyà Ọba Júdà ti há a mọ́lé síbẹ̀; pé, “Kí ló dé tí ìwọ fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ báyẹn? Tí o sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Èmi ń bọ̀ wá fi ìlú yìí fún Ọba Bábílónì, tí yóò sì gbà á.

4. Sedekáyà Ọba Júdà kò lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn Kálídéà, ṣùgbọ́n à ó mú fún Ọba Bábílónì, yóò sì bá sọ̀rọ̀ ní ojúkojú; yóò sì rí pẹ̀lú ojú rẹ̀.

5. Yóò mú Sedekáyà lọ sí Bábílónì tí yóò wà títí èmi yóò fi bẹ̀ ọ́ wò ni Olúwa wí. Tí ẹ̀yin bá bá àwọn ará Kálídéà jà, ẹ̀yin kì yóò borí wọn.’ ”

6. Jeremáyà wí pé, “ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

7. Hánámélì ọmọkùnrin Sálúmù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò tọ̀ ọ́ wá pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì; nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó sún mọ́ wọn, ẹ̀tọ́ àti ìṣe rẹ ní láti rà á.’

8. “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì tí ó wà ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’“Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí.

9. Bẹ́ẹ̀ ni; èmi ra pápá náà ní Ánátótì láti ọwọ́ Hánámélì ọmọ ẹ̀gbọ́n mi. Ó sì wọn ìwọn ṣékélì àti fàdákà mẹ́tadínlógún fún un.

10. Mo fọwọ́ sínú ìwé, mo sì dì í pa. Mo pe ẹlẹ́rìí síi, mo sì wọn fàdákà náà lórí òṣùwọ̀n.

Ka pipe ipin Jeremáyà 32