Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 31:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Ísírẹ́lì, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni Olúwa wí.

2. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idàyóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀,Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Ísírẹ́lì.”

3. Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé:“Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin;mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,

4. Èmi yóò tún gbé e yín sókè,àní a ó tún gbé e yín ró iwọ wúndíá ilẹ̀ Ísírẹ́lì.Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé,ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.

5. Ẹ ó tún dá okoní orí òkè Saáríà;àwọn àgbẹ̀ yóò sì máagbádùn èso oko wọn.

6. Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jádelórí òkè Éfráímù wí pé,‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Síónì,ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”

7. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé:“Ẹ fi ayọ̀ Kọrin sí Jákọ́bù;ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀ èdè gbogbo.Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé,‘Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là;àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Ísírẹ́lì.’

Ka pipe ipin Jeremáyà 31