Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 24:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ti kó Jékóníà ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn oníṣọ̀nà àti oníṣẹ́ ọwọ́ ti Júdà lọ sí ìgbékùn láti Jérúsálẹ́mù lọ sí ilẹ̀ àjòjì Bábílónì tán. Olúwa fi agbọ̀n èṣo ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mí tí a gbé sí iwájú pẹpẹ Olúwa.

2. Agbọ̀n kan ni èṣo ọ̀pọ̀tọ́ tí ó dára bí èyí tí ó tètè pọ́n; èkejì sì ní èṣo ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú rékọjá tí kò sì le è ṣe é jẹ

3. Nígbà náà ni Olúwa bi mí pé, “Kí ni ìwọ rí Jeremáyà?”“Èṣo ọ̀pọ̀tọ́” Mo dáhùn. “Èyí tí ó dára dára púpọ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó burú burú rékọjá tí kò sì ṣe é jẹ.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 24