Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 23:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń tú agbo ẹran mi ká tí ó sì ń pa wọ́n run!” ni Olúwa wí.

2. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ ní ti àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń darí àwọn ènìyàn mi: “Nítorí tí ẹ̀yin tú agbo ẹran mi ká, tí ẹ lé wọn dànù tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ wọ́n wò. Èmi yóò jẹ yín níyà nítorí nǹkan búburú tí ẹ ti ṣe,” ni Olúwa wí.

3. “Èmi Olúwa tìkálárami yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀ èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí síi, tí wọn ó sì pọ̀ síi.

4. Èmi ó wá olùṣọ́ àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni Olúwa wí.

5. “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,“tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dáfídì,Ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́ntí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.

6. Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Júdà là,Ísírẹ́lì yóò sì máa gbé ní aláìléwuÈyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é: Olúwa Òdodo wa.

7. “Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láàyè tí ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.’

8. Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa ń bẹ tí ó mú irú ọmọ ilé Ísírẹ́lì wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ,’ wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn.”

9. Nípa ti àwọn wòlíì èké:Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi,gbogbo egungun mi ni ó wárìrì.Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn,bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa;nítorí Olúwa àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.

10. Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyànnítorí ẹ̀gún ilẹ̀ náà gbẹ,àwọn kóríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ.Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú,wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́.

11. “Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwàbí Ọlọ́run;kódà nínú Tẹ́ḿpìlì mi ni mo rí ìwà búburú wọn,”ni Olúwa wí.

12. “Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́,a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn;níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú.Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn,ní ọdún tí a jẹ wọ́n níyà,”ni Olúwa wí.

13. “Láàrin àwọn wòlíì Saáríà,Èmi rí ohun tí ń lé ni sá:Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Báálìwọ́n sì mú Ísírẹ́lì ènìyàn mi sìnà.

Ka pipe ipin Jeremáyà 23