“Nígbà tí o bá sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yìí, tí wọ́n bá sì bi ọ́ wí pé, ‘È é ṣe tí Olúwa ṣe mú búburú yìí bá wa? Kí ni àṣìṣe tí àwa ṣe? Kínni ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa?’