Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 14:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ilẹ̀ náà sánnítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,wọ́n sì bo orí wọn.

5. Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápáfi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,torí pé kò sí koríko.

6. Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ dúró lórí òkè òfìfowọ́n sì ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ìkokòojú wọn kò rírannítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”

7. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa,wá nǹkankan ṣe sí i nítorí orúkọ rẹ.Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀ jù,a ti ṣẹ̀ sí ọ.

8. Ìrètí Ísírẹ́lì;ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú,èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náàbí arìnrìnàjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?

9. Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a mú lójijì pẹ̀lú ìyan,bí jagunjagun tí kò lágbára láti gba ni?Ìwọ wà láàárin wa, Olúwa,orúkọ rẹ ni a sì ń jẹ́;má ṣe fi wá sílẹ̀.

10. Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí:“Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri;wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu.Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n;yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí,yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 14