Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 14:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremáyà nípa ti àjàkálẹ̀-àrùn:

2. “Júdà káàánú,àwọn ìlú rẹ̀ kérorawọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn,igbe wọn sì gòkè lọ láti Jérúsálẹ́mù.

3. Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi,wọ́n lọ sí ìdí àmùṣùgbọ́n wọn kò rí omi.Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo;ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn,wọ́n sì bo orí wọn.

4. Ilẹ̀ náà sánnítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,wọ́n sì bo orí wọn.

5. Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápáfi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,torí pé kò sí koríko.

6. Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ dúró lórí òkè òfìfowọ́n sì ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ìkokòojú wọn kò rírannítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 14