Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 13:23-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ǹjẹ́ Ètópíà le yí àwọ̀ rẹ̀ padà?Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà?Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere.

24. “N ó fọ́n ọn yín ká bí i ìyàngbòtí ẹ̀fúùfù ilẹ̀ aṣálẹ̀ ń fẹ́.

25. Èyí ni ìpín tìrẹ;tí mo ti fi sílẹ̀ fún ọ,”ni Olúwa wí,“nítorí ìwọ ti gbàgbé mití o sì gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọlọ́run àjèjì.

26. N ó sí aṣọ lójú rẹkí ẹ̀sín rẹ le hàn síta

27. ìwà àgbèrè àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́,àìlójútì aṣẹ́wó rẹ!Mo ti rí ìwà ìkórìíra rẹlórí òkè àti ní pápá.Ègbé ni fún ọ ìwọ Jérúsálẹ́mù!Yóò ti pẹ́ tó tí o ó fi máa wà ní àìmọ́?”

Ka pipe ipin Jeremáyà 13