Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 13:14-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni Olúwa wí: Èmi kì yóò dáríjìn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti má a pa wọ́n run.’ ”

15. Gbọ́ kí o sì fetísílẹ̀,ẹ má ṣe gbéraga,nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

16. Ẹ fi ògo fún Olúwa Ọlọ́run yín,kí ó tó mú òkùnkùn wá,àti kí ó tó mú ẹsẹ̀ yín tàsélórí òkè tí ó ṣókùnkùn,Nígbà tí ẹ̀yin sì ń retí ìmọ́lẹ̀,òun yóò sọ ọ́ di òjìji yóò si ṣe bi òkùnkùn biribiri.

17. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀,Èmi yóò sunkún ní ìkọ̀kọ̀nítorí ìgbéraga yín;Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò,tí omi ẹkún, yóò sì máa ṣàn jáde,nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.

18. Sọ fún Ọba àti ayaba pé,“Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀,ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín,adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.”

19. Àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà ní Négéfì ni à ó tì pa,kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti sí wọn.Gbogbo Júdà ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn,gbogbo wọn ni a ó kó lọ pátapáta.

20. Gbé ojú rẹ sókè,kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá.Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà;àgùntàn tí ò ń mú yangàn.

21. Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹàwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà.Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọbí aboyún tó ń rọbí?

22. Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè“Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?”Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀ni aṣọ rẹ fi fàyatí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe.

23. Ǹjẹ́ Ètópíà le yí àwọ̀ rẹ̀ padà?Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà?Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere.

Ka pipe ipin Jeremáyà 13