Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 11:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Ísírẹ́lì àti Júdà ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí fún Báálì.

18. Nítorí Ọlọ́run fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí.

19. Mo ti dàbí ọ̀dọ́ àgùntàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí a mú lọ fún pípa; N kò mọ̀ pé wọ́n ti gbìmọ̀ búburú sí mi wí pé:“Jẹ́ kí a run igi àti èso rẹ̀;jẹ́ kí a gé e kúrò ní orí ilẹ̀ alààyè,kí a mọ́ lè rántí orúkọ rẹ̀ mọ́.”

20. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa àwọn ọmọ ogun,tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo,tí ó ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí àti ọkàn,jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn;nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

21. “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn arákùnrin Ánátótì tí wọ́n ń lépa ẹ̀mí rẹ̀, tí wọ́n ń wí pé, ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìwọ ó kú láti ọwọ́ wa.’

22. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun sọ pé, ‘Èmi yóò fìyà jẹ wọ́n, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn yóò tipasẹ̀ idà kú, ìyàn yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

23. Kò ní ṣẹ́ku ohunkóhun sílẹ̀ fún wọn nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí àwọn ènìyàn Ánátótì ní ọdún ìjìyà wọn.’ ”

Ka pipe ipin Jeremáyà 11