Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 11:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àwọn ìlú Júdà àti àwọn ará Jérúsálẹ́mù yóò lọ kégbe sí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sun tùràrí sí; àwọn òrìṣà náà kò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbà tí ìpọ́nju òhún bá dé.

13. Bí iye àwọn ìlú yín ṣe pọ̀ tó náà ni àwọn òrìṣà yín. Ìwọ Júdà: àwọn pẹpẹ tí o ti pèsè fún jíjó tùràrí sí àwọn Báálì, òrìṣà yẹ̀yẹ́ sì pọ̀ bí iye òpópó tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù.’

14. “Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé Èmi kò ní dẹtí sí wọn ní ìgbà ìpọ́njú.

15. “Kí ni àyànfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹ́ḿpìlì mi,bí ó ṣe ń hu oríṣiríṣi ìwà àrékérekè?Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀?Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ ibi rẹ̀,inú rẹ̀ yóò máa dùn.”

16. Olúwa pè ọ́ ní igi ólífìpẹ̀lú èṣo rẹ tí ó dára ní ojú.Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líleọ̀wọ́ iná ni yóò sun úntí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì dá.

17. Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Ísírẹ́lì àti Júdà ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí fún Báálì.

18. Nítorí Ọlọ́run fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí.

Ka pipe ipin Jeremáyà 11