Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 10:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀,ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ tóbi síta nípa òye rẹ̀.

13. Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omilọ́run a sì pariwo, ó mú kí ìkuùkù rusókè láti òpin ayé: ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.

14. Gbogbo ènìyàn jẹ́ aláìlóye àti aláìnímọ̀,ojú sì ti gbogbo alágbára pẹ̀lú ère rẹ̀,èrú ni ère rẹ̀, kò sì sí ẹ̀mí nínú wọn.

15. Asán ni wọ́n, iṣẹ́ yẹ̀yẹ́ sì ni;nígbà tí ìdájọ́ wọn bá dé, wọn yóò ṣègbé.

16. Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jákọ́bù kò sìdàbí èyí, nítorí òun ni ó ṣẹ̀dáohun gbogbo àti Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ẹ̀yà ìjogún rẹ̀. Olúwa àwọn ọmọogun ni orúkọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremáyà 10