Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 1:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wòó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀ èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti má a kọ́, àti láti máa gbìn.

11. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé“Kí ni o rí Jeremáyà?” Mo sì dáhùn wí pé “Mo rí ẹ̀ka igi álímọ́ńdi”

12. Olúwa sì wí fún mi pé, “ó ti rí i bí ó se yẹ, torí pé mo ti ń sọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúsẹ.”

13. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ́kèjì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá.

Ka pipe ipin Jeremáyà 1