Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 1:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremáyà ọmọ Hílíkíyà ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Ánátótì ní gbígbé ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì.

2. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Jòṣáyà ọmọ Ámónì Ọba Júdà,

3. Àti títí dé àsìkò Jéhóákímù ọmọ Jòṣáyà Ọba Júdà, títí dé oṣù kaàrún ọdún kọkànlá Ṣedekáyà ọmọ Jòṣáyà Ọba Júdà, nígbà tí àwọn ará Jérúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn.

4. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé,

5. Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́,kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀.Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀ èdè.

6. Mo sọ pé Háà! Olúwa tí ó pọ̀ ní ipá, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin Jeremáyà 1