Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 9:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀.Nítorí ní àwòrán Ọlọ́runni Ọlọ́run dá ènìyàn.

7. Ṣùgbọ́n ní tiyín, ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ máa gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀, kí ẹ sì pọ̀ sí i lórí rẹ̀.”

8. Ọlọ́run sì wí fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé:

9. “Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú àwọn ìran yín tí ń bọ̀ lẹ́yìn.

10. Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbáà ṣe ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé.

11. Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run.”

12. Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrin èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀:

13. Mo ti fi òṣùmàrè sí ojú ọ̀run, yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrin èmi àti ayé.

14. Nígbàkúgbà tí mo bá mú kí òjò sú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní ojú ọ̀run.

15. Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrin èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 9