Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 9:24-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Nígbà tí ọtí dá kúrò ní ojú Nóà, tí ó sì mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ àti ohun tí Ámù ọmọ rẹ̀ ṣe sí i.

25. Ó wí pé:“Ègún ni fún Kénánì.Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máaṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀.”

26. Ó sì tún wí pé;“Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run ṢémùKénánì yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣémù.

27. Ọlọ́run yóò mú Jáfétì gbilẹ̀,Jáfétì yóò máa gbé ní àgọ́ ṢémùKénánì yóò sì jẹ́ ẹrú fún-un.”

28. Nóà wà láàyè fún irínwó-ọdún-ó-dín-àádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi.

29. Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Nóà jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-ní-àádọ́ta ọdún, (950) ó sì kú.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 9