Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 7:16-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Gbogbo wọn wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà, Olúwa sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀.

17. Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i.

18. Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi.

19. Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run.

20. Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n mítà bí i méje.

21. Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn.

22. Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú.

23. Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́: ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátapáta ló ṣègbé. Nóà àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù.

24. Omi náà sì bo ilẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́ (150).

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 7