Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 7:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Nóà pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí.

2. Mú méjeméje nínú àwọn ẹran tí ó mọ́, akọ àti abo, mú méjìméjì takọ tabo nínú àwọn ẹran aláìmọ́.

3. Sì mú méjeméje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á baà lè pa wọ́n mọ́ láàyè ní gbogbo ayé.

4. Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run, kúrò lórí ilẹ̀.”

5. Nóà sì ṣe ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un.

6. Nóà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀.

7. Nóà àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì wọ inú ọkọ láti ṣá àsálà fún ìkún omi.

8. Méjìméjì ni àwọn ẹran tí ó jẹ́ mímọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà,

9. akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Nóà sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà.

10. Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé.

11. Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kéjì, tí Nóà pé ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún, ni gbogbo ìṣun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì sí sílẹ̀.

12. Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.

13. Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan-an ni Nóà àti Ṣémù, Ámù àti Jáfétì pẹ̀lú aya Nóà àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀.

14. Wọn mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 7