Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 6:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ọlọ́run sì wí fún Nóà pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípaṣẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú.

14. Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn.

15. Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òòró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́.

16. Ṣe òrùlé sí orí ọkọ̀ náà ní ìgbọ̀nwọ́ kan, sì ṣe ọkọ̀ náà ní alájà mẹ́ta, ipá kan ní ìṣàlẹ̀, ọ̀kan ní àárin àti ọ̀kan tí ó kù ní òkè, ẹ̀gbẹ́ ni kí ó ṣe ẹnu ọ̀nà ọkọ̀ náà sí.

17. Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run, lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú. Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun.

18. Ṣùgbọ́n èmi ó dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì wọ ọkọ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú aya rẹ.

19. Ìwọ yóò mú gbogbo ohun alààyè takọ tabo wá sí inú ọkọ̀ kí wọn le wà láàyè pẹ̀lú rẹ.

20. Mú onírúurú àwọn ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun tí ń rákò ní méjìméjì kí a bá lè pa wọ́n mọ́ láàyè.

21. Mú onírúurú oúnjẹ wá sínú ọkọ̀ kí o pa wọ́n mọ́ fún jíjẹ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà nínú ọkọ̀ àti ènìyàn àti ẹranko.”

22. Nóà sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 6