Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 50:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Fáráò wí pé, “Gòkè lọ, kí o sì sin baba rẹ, bí ó tí mú ọ búra.”

7. Báyìí ni Jósẹ́fù gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè Fáráò ni ó sìn ín lọ—àwọn ènìyàn pàtàkì pàtàkì ilé rẹ̀, àti àwọn ènìyàn pàtàkì pàtàkì ilẹ̀ Éjíbítì.

8. Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Jóṣẹ́fù àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Gósénì.

9. Kẹ̀kẹ́ ẹsin àti àwọn ẹlẹ́sin pẹ̀lú gòkè lọ. Àìmọye ènìyàn ni ó lọ.

10. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà Átadì, ní ẹ̀bá Jọ́dánì, wọn pohùn réré ẹkún; Níbẹ̀ ni Jósẹ́fù sì tún dúró ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ méje.

11. Nígbà tí àwọn ará Kénánì tí ń gbé níbẹ̀ ri i bí wọ́n ti ń sọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Átadì, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Éjíbítì ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Mísíráímù (Ìsọ̀fọ̀ àwọn ará Éjíbítì). Kò sì jìnnà sí Jọ́dánì.

12. Báyìí ni àwọn ọmọ Jákọ́bù ṣe ohun tí baba wọn páṣẹ fún wọn.

13. Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénánì, wọ́n sì sin-ín sínú ihò àpáta tí ó wà ní oko Makipélà, ní tòsí i Mámúrè tí Ábúráhámù rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Éfúrónì ará Hítì, pẹ̀lú ilẹ̀ náà.

14. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú baba rẹ̀ tan, Jóṣẹ́fù padà sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn mìíràn tí ó tẹ̀lé e lọ láti sin baba rẹ̀.

15. Nígbà tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù rí i pé baba wọn kú, wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ bí ó bá ṣe pé Jósẹ́fù sì fi wá sínú ńkọ́, tí ó sì fẹ́ gbẹ̀ṣan gbogbo aburú tí a ti ṣe sí i?”

16. Nítorí náà wọ́n ránṣẹ́ sí Jósẹ́fù wí pé, “Baba rẹ fi àṣẹ yìí sílẹ̀ kí ó tó lọ wí pé:

17. ‘Èyí ni kí ẹ̀yin kí ó sọ fún Jóṣẹ́fù: Mo bẹ̀ ọ́ kí o dáríjìn àwọn arákùnrin rẹ, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti aburú tí wọ́n ṣe sí ọ, èyí tí ó mú ibi bá ọ’. Nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run baba rẹ jìn wọ́n.” Nígbà tí iṣẹ́ ti wọ́n rán dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Jósẹ́fù sunkún.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 50