Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 50:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jósẹ́fù sì subú lé baba rẹ̀, ó sunkún, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnu.

2. Nígbà náà ni Jósẹ́fù pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Ísírẹ́lì baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀,

3. Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Éjíbítì sì sọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́.

4. Nígbà tí ọjọ́ ìṣọ̀fọ̀ náà kọjá. Jósẹ́fù wí fún àwọn ará ilé Fáráò pé, “Bí mo bá bá ojúrere yín pàdé, ẹ bámi sọ fún Fáráò.

5. ‘Baba mi mú mi búra ó sì wí fún mi pé, “Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú: sin mi sínú ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kénánì.” Nísinsin yìí, jẹ́ kí n lọ kí n sì sìnkú baba mi, lẹ́yìn náà èmi yóò padà wa.’ ”

6. Fáráò wí pé, “Gòkè lọ, kí o sì sin baba rẹ, bí ó tí mú ọ búra.”

7. Báyìí ni Jósẹ́fù gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè Fáráò ni ó sìn ín lọ—àwọn ènìyàn pàtàkì pàtàkì ilé rẹ̀, àti àwọn ènìyàn pàtàkì pàtàkì ilẹ̀ Éjíbítì.

8. Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Jóṣẹ́fù àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Gósénì.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 50