Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 49:27-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. “Bẹ́ńjámínì jẹ́ ìkookò tí ó burú.Ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran-ọdẹ rẹ,ní àsáálẹ́, ó pín ìkógun.”

28. Gbogbo ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá, èyí sì ni ohun tí baba wọn sọ fún wọn nígbà tí ó súre fún wọn, tí ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìbùkún tí ó tọ́ sí i.

29. Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́fẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hítì ará Éfúrónì.

30. Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Mákípélà, nítòsí Mámúrè ní Kénánì, èyí tí Ábúráhámù rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀-ìsìnkú lọ́wọ́ Éfúrónì ará Hétì pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀.

31. Níbẹ̀ ni a sin Ábúráhámù àti aya rẹ̀ Ṣárà sí, níbẹ̀ ni a sin Ísáákì àti Rèbékà aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Líà sí.

32. Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hítì.”

33. Nígbà tí Jákọ́bù ti pàṣẹ yìí fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó gbé ẹṣẹ rẹ̀ sókè sórí ibùsùn, ó sì kú, a sì ko jọ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 49