Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 49:23-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Pẹ̀lú ìkorò,àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́,wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra,

24. Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára,ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le,nítorí ọwọ́ alágbára Jákọ́bù,nítorí olútọ́jú àti aláàbò àpáta Ísírẹ́lì.

25. Nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́,nítorí Olódùmarè tí ó bù kún ọ,pẹ̀lú láti ọ̀run wá,ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìṣàlẹ̀,ìbùkún ti ọmú àti ti inú,

26. ìbùkún baba rẹ pọ̀ púpọ̀ju ìbùkún àwọn òkè ńlá ìgbàanì,ju ẹ̀bùn ńlá àwọn òkè láéláé.Jẹ́ kí gbogbo èyí sọ̀kalẹ̀ sí orí Jóṣẹ́fù,lé ìpéǹpéjú ọmọ aládé láàrin arákùnrin rẹ̀.

27. “Bẹ́ńjámínì jẹ́ ìkookò tí ó burú.Ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran-ọdẹ rẹ,ní àsáálẹ́, ó pín ìkógun.”

28. Gbogbo ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá, èyí sì ni ohun tí baba wọn sọ fún wọn nígbà tí ó súre fún wọn, tí ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìbùkún tí ó tọ́ sí i.

29. Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́fẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hítì ará Éfúrónì.

30. Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Mákípélà, nítòsí Mámúrè ní Kénánì, èyí tí Ábúráhámù rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀-ìsìnkú lọ́wọ́ Éfúrónì ará Hétì pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀.

31. Níbẹ̀ ni a sin Ábúráhámù àti aya rẹ̀ Ṣárà sí, níbẹ̀ ni a sin Ísáákì àti Rèbékà aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Líà sí.

32. Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hítì.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 49