Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 49:13-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. “Ṣébúlúnì yóò máa gbé ní etí òkun,yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi,agbégbé rẹ yóò tàn ká títí dé Ṣídónì.

14. “Ísákárì jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ alágbáratí ó sùn sílẹ̀ láàrin àpò ẹrù méjì.

15. Nígbà tí ó bá rí bí ibi ìsinmi òun ti dára tó,àti bí ilẹ̀ rẹ̀ ti ní ìdẹ̀ra tó,yóò tẹ èjìká rẹ̀ ba láti ru àjàgà,yóò sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ipá.

16. “Dánì yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

17. Dánì yóò jẹ́ ejo ni pópónààti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà,tí ó bu ẹsin jẹ ní ẹṣẹ̀,kí ẹni tí n gùn-un bá à le è subú sẹ́yìn.

18. “Mo ń dúró de ìtúsilẹ̀ rẹ, Olúwa

19. “Ẹgbẹ́-ogun àwọn ẹlẹ́sin yóò kọ lu Gádì,ṣùgbọ́n yóò kọ lu wọ́n ní gìgíṣẹ̀ wọn.

20. “Oúnjẹ Áṣérì yóò dára;yóò ṣe àṣè tí ó yẹ fún ọba.

21. “Náfútalì yóò jẹ́ abo àgbọ̀nríntí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ daradara.

22. “Jóṣẹ́fù jẹ́ àjàrà eléṣo,àjàrà eléṣo ní etí odò,tí ẹ̀ka rẹ̀ gun orí odi.

23. Pẹ̀lú ìkorò,àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́,wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra,

24. Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára,ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le,nítorí ọwọ́ alágbára Jákọ́bù,nítorí olútọ́jú àti aláàbò àpáta Ísírẹ́lì.

25. Nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́,nítorí Olódùmarè tí ó bù kún ọ,pẹ̀lú láti ọ̀run wá,ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìṣàlẹ̀,ìbùkún ti ọmú àti ti inú,

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 49