Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 49:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Jákọ́bù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò sẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún-un yín.

2. “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jákọ́bù;Ẹ fetí sí Ísírẹ́lì baba yín.

3. “Rúbẹ́nì, ìwọ ni àkọ́bí mi,agbára mi, ìpìlẹṣẹ̀ ipá mi,títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára.

4. Ẹni ríru bí omi òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́,nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ,lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́(ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lò pọ̀).

5. “Símónì àti Léfì jẹ́ arákùnrin—idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára.

6. Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn,kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn,nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn,wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 49