Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 47:14-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Jósẹ́fù gba gbogbo owó tí ó wà ní ilẹ̀ Éjíbítì àti Kénánì ní ìpààrọ̀ fún ti ọkà tí wọn ń rà, ó sì mú owó náà wá sí ààfin Fáráò.

15. Nígbà tí owó wọn tán pátapáta ní Éjíbítì àti Kénánì, gbogbo Éjíbítì wá bá Jósẹ́fù, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ, èéṣe tí a ó fi kú ní ojú rẹ? Gbogbo owó wa ni a ti ná tan.”

16. Jósẹ́fù wí pé, “Ẹ mú àwọn ẹran-ọ̀sìn yín wá, èmi yóò fún un yín ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran-ọ̀sìn yín, níwọ̀n bí owó yín ti tan.”

17. Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn tọ Jósẹ́fù wá, ó sì fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹsin, àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó sì mú wọn la ọdún náà já, tí ó ń fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran-ọ̀sìn wọn.

18. Nígbà tí ọdún náà parí, wọn padà tọ̀ ọ́ wá ní ọdún tí ó tẹ̀le, wọn wí pé, “A kò le fi pamọ́ fun olúwa wa pé níwọ̀n bí owó wa ti tan tí gbogbo ẹran-ọ̀sìn wa sì ti di tirẹ̀ pé, kò sí ohunkóhun tó kù fún olúwa wa bí kò ṣe ara wa àti ilẹ̀ wa.

19. Èése tí àwa yóò fi parun lójú rẹ, ra àwa tìkárawa àti ilẹ̀ wa ní ìpààrọ̀ fún oúnjẹ, àwa àti ilẹ̀ wa yóò sì wà nínú ìgbékùn Fáráò. Fún wa ni oúnjẹ kí àwa kí ó má ba à kú, kí ilẹ̀ wa má ba à di ahoro.”

20. Nítorí náà Jósẹ́fù ra gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní Éjíbítì fún Fáráò, kò sí ẹnìkan tí ó sẹ́kù ní Éjíbítì tí kò ta ilẹ̀ tirẹ̀ nítorí ìyàn náà mú jù fún wọn. Gbogbo ilẹ̀ náà sì di ti Fáráò,

21. Jósẹ́fù sì sọ gbogbo ará Éjíbítì di ẹrú láti igun kan dé èkejì

22. Ṣùgbọ́n sá, kò ra ilẹ̀ àwọn àlùfáà, nítorí wọ́n ń gba ìpín oúnjẹ lọ́wọ́ Fáráò, wọn sì ní oúnjẹ tí ó tó láti inú ìpín tí Fáráò ń fún wọn. Ìdí nìyí tí wọn kò fi ta ilẹ̀ wọn.

23. Jósẹ́fù wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín tan lónìí fún Fáráò, irúgbìn rè é, ẹ lọ gbìn ín sí ilẹ̀ náà.

24. Ṣùgbọ́n nígbà tí ire oko náà bá jáde, ẹ ó mú ìdá kan nínú ìdá márùn-ún rẹ̀ fún Fáráò. Ẹ le pa ìdá mẹ́rin tókù mọ́ fún ara yín àti ìdílé yín àti àwọn ọmọ yín.”

25. Wọ́n dá á lóhùn pé, “O ti gbà wá là, Ǹjẹ́ kí a rí ojúrere níwájú olúwa wa, àwa yóò di ẹrú Fáráò.”

26. Nítorí náà Jósẹ́fù sọ ọ́ di òfin nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ni Éjíbítì, ó sì wà bẹ́ẹ̀ di òni olónìí-pé, ìdá kan nínú ìdá márùn-ún irè oko jẹ́ ti Fáráò, ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Fáráò.

27. Àwọn ará Ísírẹ́lì sì tẹ̀dó sí Éjíbítì ní agbégbé Gósénì. Wọ́n ní ohun-ìní fún ara wọn, wọ́n sì bí sí i tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n pọ̀ si gidigidi ní iye.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 47