Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 46:13-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Àwọn ọmọkùnrin Ísákárì!Tólà, Pútà, Jásíbù àti Ṣímírónì.

14. Àwọn ọmọkùnrin Ṣébúlúnì:Ṣérédì, Élónì àti Jáhálélì.

15. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Líà tí ó bí fún Jákọ́bù ní Padani-Árámù yàtọ̀ fún Dínà ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́talélọ́gbọ̀n. (35) lápapọ̀.

16. Àwọn ọmọkùnrin Gádì:,Ṣífónì, Ágì, Ṣúnì, Ésíbónì, Érì, Áródì, àti Árélì.

17. Àwọn ọmọkùnrin Ásérì:Ímínà, Íṣífà, Íṣífì àti Béríà. Arábìnrin wọn ni Ṣérà.Àwọn ọmọkùnrin Béríà:Ébérì àti Málíkíélì.

18. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jákọ́bù bí nípaṣẹ̀ Ṣílípà, ẹni tí Lábánì fi fún Líà ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún (16) lápapọ̀.

19. Àwọn ọmọkùnrin Rákélì aya Jákọ́bù:Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.

20. Ní Éjíbiti, Áṣénátù ọmọbìnrin Pọ́tíférà, alábojútó àti àlùfáà Ónì, bí Mánásè àti Éfúráímù fún Jósẹ́fù.

21. Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì:Bélà, Békérì, Áṣíbélì, Gérà, Náámánì, Éhì, Rósì, Múpímù, Húpímù àti Árídà.

22. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Rákẹ́lì bí fún Jákọ́bù. Wọ́n jẹ́ mẹ́rìnlá (14) lápapọ̀.

23. Àwọn ọmọ Dánì:Úsímù.

24. Àwọn ọmọ Náfítalì:Jáháṣíè, Gúnì, Jésérì, àti Ṣílémù.

25. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Bílíhà ẹni tí Lábánì fi fún Rákélì ọmọ rẹ̀ bí fún Jákọ́bù. Wọ́n jẹ́ méje lápapọ̀.

26. Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jákọ́bù sí Éjíbítì, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láì ka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìndín-ní-àadọ́rin (66).

27. Pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Jósẹ́fù ní Éjíbítì àwọn ará ilé Jákọ́bù tí ó lọ sí Éjíbítì jẹ́ àádọ́rin (70) lápapọ̀

28. Jákọ́bù sì rán Júdà ṣáájú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Jósẹ́fù, kí wọn báà le mọ ọ̀nà Gósénì. Nígbà tí wọ́n dé agbégbé Gósénì,

29. Jósẹ́fù tọ́jú kẹ̀kẹ́-ẹsin rẹ̀ ó sì lọ sí Gósénì láti pàdé Ísírẹ́lì baba rẹ̀. Bí Jósẹ́fù ti dé iwájú baba rẹ̀, ó dì mọ́ baba rẹ̀ ó sì sunkún fún ìgbà pípẹ́.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 46