Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 45:23-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó ránṣẹ́ sí baba rẹ̀: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru àwọn ohun mèremère ilẹ̀ Éjíbítì àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti oríṣìíríṣìí oúnjẹ.

24. Nígbà náà ni ó rán àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe ń pínyà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jà ní ọ̀nà o!”

25. Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì wá sí ọ̀dọ̀ Jákọ́bù baba wọn ní ilẹ̀ Kénánì.

26. Wọn wí fún un pé, “Jósẹ́fù sì wà láàyè! Kódà òun ni alákòóṣo ilẹ̀ Éjíbítì” Ẹnu ya Jákọ́bù, kò sì gbà wọ́n gbọ́

27. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Jósẹ́fù ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Jósẹ́fù fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jákọ́bù, baba wọn ṣọ.

28. Ísírẹ́lì sì wí pé, “Mo gbà dájúdájú wí pé, Jósẹ́fù ọmọ mi wà láàyè. Èmi ó lọ rí i kí n tó kú.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 45