Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 45:10-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìwọ yóò gbé ní agbégbé Gósénì, ìwọ kì yóò jìnnà sí mi-ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ àti agbo màlúù rẹ àti gbogbo ohun tí ìwọ ní.

11. Èmi yóò pèṣè fún yín níbẹ̀. Nítorí ó sì ku ọdún márùn ún gbáko ti ìyàn yóò fi mú. Kí ìwọ àti ilé rẹ àti ohun tí í ṣe tìrẹ má baà di aláìní.

12. “Ẹ̀yin fúnra yín àti Bẹ́ńjámínì arákùnrin mi pẹ̀lú rí i pé, lóòótọ́ lóòótọ́, èmi Jósẹ́fù ni mo ń bá a yín sọ̀rọ̀.

13. Ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ọlá tí a fún mi ní ilẹ̀ Éjíbítì àti ohun gbogbo tí ẹ̀yin ti rí, kí ẹ sì mú baba mi tọ̀ mí wá sí ìhín yìí kíákíá.”

14. Nígbà náà ni ó dì mọ́ Bẹ́ńjámínì arákùnrin rẹ̀, ó sì sunkún, Bẹ́ńjámínì náà sì dì mọ́ ọn, pẹ̀lú omijé lójú.

15. Ó sì tún fẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì sunkún sí wọn lára. Lẹ́yìn èyí, Jósẹ́fù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀.

16. Nígbà tí ìròyìn náà dé ààfin Fáráò pé àwọn arákùnrin Jósẹ́fù dé, inú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ dùn.

17. Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé, “Wí fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Èyí ni kí ẹ ṣe: Ẹ di ẹrù lé ẹranko yín kí ẹ sì padà sí ilẹ̀ Kénánì,

18. kí ẹ sì mú baba yín àti ìdílé yín tọ̀ mí wá. Èmi yóò fún un yín ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Éjíbítì, ẹ̀yin yóò sì le è gbádùn ilẹ̀ yìí.’

19. “A pàṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe èyí: Ẹ mú kẹ̀kẹ́ ẹrù láti ilẹ̀ Éjíbítì fún àwọn ọmọ yín àti àwọn aya yín. Kí ẹ sì mú baba yín tọ mí wá.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 45